Joshua 8:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọn farapamọ́ bá yára dìde ní ibi tí wọ́n wà. Bí Joṣua ti na ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sáré wọ inú ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára sọ iná sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o ba si dide kánkan kuro ni ipò wọn, bi o si ti nàwọ́ rẹ̀, nwọn sare, nwọn si wọ̀ ilu na lọ, nwọn si gbà a; nwọn si yára tinabọ ilu na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré ṣíwájú. Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́.