Joshua 8:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Ai bojú wẹ̀yìn, tí wọ́n rí i tí èéfín yọ ní ìlú wọn, wọn kò ní agbára mọ́ láti sá síhìn-ín tabi sọ́hùn-ún, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n sá gba ọ̀nà aṣálẹ̀ lọ yíjú pada sí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ọkunrin Ai boju wo ẹhin wọn, kiyesi i, nwọn ri ẹ̃fi ilu na ngòke lọ si ọrun, nwọn kò si lí agbara lati gbà ihin tabi ọhún sálọ: awọn enia ti o sá lọ si aginjù si yipada si awọn ti nlepa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Áì bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, àyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Ísírẹ́lì tí wọ́n tí ń sálọ sí ihà ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn.