Joshua 8:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti fi idà pa gbogbo àwọn ará Ai tán ninu aṣálẹ̀, ní ibi tí wọ́n ti ń lé wọn lọ, wọ́n pada sí ìlú Ai, wọ́n sì fi idà pa gbogbo wọn patapata.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Israeli pari pipa gbogbo awọn ara ilu Ai ni igbẹ́, ati ni aginjù ni ibi ti nwọn lé wọn si, ti gbogbo wọn si ti oju idà ṣubu, titi a fi run wọn, ni gbogbo awọn ọmọ Israeli pada si Ai, nwọn si fi oju idà kọlù u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ísírẹ́lì parí pípa àwọn ọkùnrin Áì ní pápá àti ní ihà ní ibi tí wọ́n ti lépa wọn lọ, nígbà tí wọ́n pa gbogbo wọn tan, gbogbo àwọn Ísírẹ̀lì sì padà sí Áì, wọ́n sì pa àwọn tí ó ṣẹ́kù síbẹ̀.