Joshua 8:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó so ọba Ai kọ́ sórí igi kan títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀, Joṣua pàṣẹ pé kí wọn já òkú rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì wọ́ ọ sí ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta jọ lé e lórí, òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba Ai li o si so rọ̀ lori igi titi di aṣalẹ: bi õrùn si ti wọ̀, Joṣua paṣẹ ki a sọ okú rẹ̀ kuro lori igi kalẹ, ki a si wọ́ ọ jù si atiwọ̀ ibode ilu na, ki a si kó òkiti nla okuta lé e lori, ti mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì gbé ọba Áì kọ́ orí igi, ó sì fi kalẹ̀ síbẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. Bí òòrùn sì ti wọ̀ ni Jóṣúà pàṣẹ fún wọn láti sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní orí igi, kí wọn sì wọ́ ọ jù sí àtiwọ ẹnu ibodè ìlú náà. Wọ́n sì kó òkítì òkúta ńlá lé e ní orí, èyí tí ó wà títí di òní yìí.