Joshua 8:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
bí Mose iranṣẹ OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli ati gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ ọ́ sí inú ìwé òfin Mose pé, “Pẹpẹ tí wọ́n fi òkúta tí wọn kò gbẹ́ kọ́, tí ẹnikẹ́ni kò gbé ohun èlò irin sókè láti gbẹ́ òkúta rẹ̀.” Wọ́n rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA lórí rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwé ofin Mose, pẹpẹ odidi okuta, lara eyiti ẹnikan kò fi irin kan: nwọn si ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA, nwọn si ru ẹbọ alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
gẹ́gẹ́ bí Móṣè ìránṣẹ́ OLÚWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó sì kọ́ ọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú Iwé Òfin Móṣè, pẹpẹ odindi òkúta, èyí tí ẹnìkan kò fi ohun èlò irin kàn rí. Wọ́n sì rú ọrẹ ẹbo ṣísun àti ọrẹ àlàáfíà ní orí i rẹ̀ sí OLÚWA.