Joshua 8:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo Israẹli, ati onílé, ati àlejò, gbogbo àwọn àgbààgbà, ati àwọn olórí, ati àwọn aṣiwaju dúró ní òdìkejì Àpótí Majẹmu OLUWA, níwájú àwọn alufaa, ọmọ Lefi, tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu náà. Ìdajì wọn dúró níwájú òkè Ebali bí Mose, iranṣẹ OLUWA, ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo Israeli, ati awọn àgba wọn, ati awọn olori, ati awọn onidajọ wọn, duro li apa ihin ati li apa ọhún apoti ẹrí niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi, ti o rù apoti majẹmu OLUWA, ati alejò ati ibilẹ; àbọ wọn kọjusi òke Gerisimu; ati àbọ wọn kọjusi òke Ebali, gẹgẹ bi Mose iranṣẹ OLUWA ti paṣẹ rí, pe ki nwọn ki o sure fun awọn enia Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo Ísírẹ́lì, àlejò àti ọmọ ìlú, pẹ̀lú àwọn àgbà, olórí àti onídàájọ́ dúró ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àpótí ẹ̀rí OLÚWA tí ó kọjú sí àwọn àlùfáà tí ó rù ú, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì. Ìdajì àwọn ènìyàn náà dúró ní Òkè Gérísímù, àwọn ìdajì si dúró ni òkè Ébálì, gẹ́gẹ́ bí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA ti pàṣẹ rí, pé kí wọn súre fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.