Joshua 8:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò sí ohun tí Mose pa láṣẹ tí Joṣua kò kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ati ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati àlejò tí wọ́n wà ní ààrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo eyiti Mose palaṣẹ, ti Joṣua kò kà niwaju gbogbo ijọ Israeli, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹrẹ, ati awọn alejò ti nrìn lãrin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sí ọ̀rọ̀ kan nínú gbogbo èyí tí Mósè pàṣẹ, tí Jósúà kò kà ní iwájú gbogbo àjọ Ísírẹ́lì, títí fi kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárin wọn.