Joshua 8:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joṣua bá rán wọn ṣiwaju, wọ́n sì lọ sí ibi tí wọn yóo fara pamọ́ sí ní ìwọ̀ oòrùn Ai, láàrin Ai ati Bẹtẹli. Ṣugbọn Joṣua wà pẹlu àwọn eniyan ní gbogbo òru ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni Joṣua ṣe rán wọn lọ: nwọn lọ iba, nwọn si joko li agbedemeji Beti-eli ati Ai, ni ìha ìwọ-õrùn Ai: ṣugbọn Joṣua dó li oru na lãrin awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jóṣúà rán wọn lọ. Wọ́n sì lọ sí ibùba, wọ́n sì sùn ní àárin Bétélì àti Áì, ní ìwọ̀-oòrùn Áì. Ṣùgbọ́n Jóṣúà wá dúró pẹ̀lú àwọn ènìyan ní orú ọjọ náà.