Joshua 9:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wò ó! Burẹdi wa nìyí, ó gbóná nígbà tí a dì í nílé fún ìrìn àjò yìí ní ọjọ́ tí a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti gbẹ, ó sì ti bu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Àkara wa yi ni gbigbona li a mú u fun èse wa, lati ile wa wá, li ọjọ́ ti a jade lati tọ̀ nyin wá; ṣugbọn nisisiyi, kiyesi i, o gbẹ, o si bu:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbígbóná ní a mú oúnjẹ ní ojí nílé ní oji tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsinyí.