Joshua 9:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Joṣua bá wọn dá majẹmu alaafia, pé, àwọn kò ní pa wọ́n, àwọn àgbààgbà Israẹli sì búra fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joṣua si bá wọn ṣọrẹ, o si bá wọn dá majẹmu lati da wọn si: awọn olori ijọ enia fi OLUWA Ọlọrun Israeli bura fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jósúà ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wọn láti dá wọn sí, àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn fi ọwọ́ sí àdéhùn náà nípa ṣíṣe ìbúra.