Joshua 9:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn àgbààgbà bá wí fún wọn pé, “Ẹ má pa wọ́n.” Àwọn àgbààgbà Israẹli bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà di aṣẹ́gi ati apọnmi fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn olori si wi fun wọn pe, Ẹ da wọn si: nwọn si di aṣẹ́gi ati apọnmi fun gbogbo ijọ; gẹgẹ bi awọn olori ti sọ fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n tẹ̀ṣíwájú, “Ẹ dá wọn sí, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn jẹ́ gégigégi àti apọnmi fún gbogbo ìlú.” Àwọn àgbààgbà náà sì mú ìlérí wọn sẹ fún wọn.