Jude 1:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi a máa sọ ìsọkúsọ nípa ohunkohun tí kò bá ti yé wọn. Àwọn nǹkan tí ó bá sì yé wọn, bí nǹkan tíí yé ẹranko ni. Ohun tí ń mú ìparun bá wọn nìyí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn awọn wọnyi nsọ̀rọ-òdi si ohun gbogbo ti nwọn kò mọ̀: ṣugbọn ohun gbogbo ti nwọn mọ̀ nipa ẹda, bi ẹranko tí kò ni iyè, ninu nkan wọnyi ni nwọn di ẹni iparun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀ òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa ìròfún-ara, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípaṣẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.