Jude 1:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egbé ni fun wọn! nitoriti nwọn ti rìn li ọ̀na Kaini, nwọn si fi iwọra súré sinu ìṣina Balaamu nitori ère, nwọn si ṣegbé ninu iṣọtẹ̀ Kora.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ègbé ni fún wọn! Nítorí tí wọ́n ti rìn ní ọ̀nà Káínì, wọ́n sì fi ìwọra súré sínú ìsìnà Bálámù nítorí ère, wọn ṣègbé nínú ìṣọ̀tẹ̀ Kórà.