Jude 1:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bàsèjẹ́ ni wọ́n jẹ́ ninu àsè ìfẹ́ ìjọ, wọn kò ní ọ̀wọ̀ nígbà tí ẹ bá jọ ń jẹ, tí ẹ jọ ń mu. Ara wọn nìkan ni wọ́n ń tọ́jú bí olùṣọ́-aguntan tí ń tọ́jú ara rẹ̀ dípò aguntan. Wọ́n dàbí ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń gbá kiri tí kò rọ òjò. Igi tí kò ní èso ní àkókò ìkórè ni wọ́n, wọ́n ti kú sára. Nígbà tí ó bá ṣe, wọn á wó lulẹ̀ tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi li o jẹ abawọn ninu àse ifẹ nyin, nigbati nwọn mba nyin jẹ ase, awọn oluṣọ-agutan ti mbọ́ ara wọn laibẹru: ikũku laini omi, ti a nti ọwọ afẹfẹ gbá kiri: awọn igi alaileso li akoko eso, nwọn kú lẹ̃meji, a fà wọn tu ti gbongbo ti gbongbo;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí ní ó jẹ́ àbàwọ́n nínú àṣè ìfẹ́ yín, nígbà tí wọ́n ń bá yín jẹ àsè, àwọn olùsọ́ àgùntàn ti ń bọ́ ara wọn láìbẹ̀rù. Wọ́n jẹ́ ìkùùkuu láìrọ òjò, tí a ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ gbá kiri; àwọn igi aláìléso ní àkókò èso, wọ́n kú lẹ́ẹ̀méjì, a sì fà wọn tú ti-gbòǹgbò-ti-gbòǹgbò.