Jude 1:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nípa àwọn wọnyi ni Enọku tí ó jẹ́ ìran keje sí Adamu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, “Mo rí Oluwa tí ó dé pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun àwọn angẹli rẹ̀ mímọ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi pẹlu ni Enoku, ẹni keje lati ọdọ Adamu, sọtẹlẹ fun, wipe Kiyesi i, Oluwa mbọ̀ pẹlu ẹgbẹgbãrun awọn enia rẹ̀ mimọ́,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni Énọ́kù, ẹni keje láti ọ̀dọ̀ Ádámù, sọ̀tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé “Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́,