Jude 1:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi lónìí. Àlá tí wọn ń lá, fún ìbàjẹ́ ara wọn ni. Wọ́n tàpá sí àwọn aláṣẹ. Wọ́n ń sọ ìsọkúsọ sí àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí ó lógo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bakanna ni awọn wọnyi pẹlu nsọ ara di ẽri ninu àlá wọn, nwọn si ngan ijoye, nwọn si nsọ̀rọ buburu si awọn ọlọlá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjoye, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búbúrú sí àwọn ọlọ́lá.