Judges 1:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Ẹ̀bùn kan ni mo fẹ́ tọrọ. Ṣé o mọ̀ pé ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni o fún mi; nítorí náà, fún mi ní orísun omi pẹlu rẹ̀.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí ó wà ní òkè ati ní ìsàlẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun u pe, Ta mi lọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fi isun omi fun mi pẹlu. Kalebu si fi ìsun òke ati isun isalẹ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ákíṣà sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojú rere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní Gúúsù (gúṣù) fún mi ní ìṣun omi náà pẹ̀lú.” Kélẹ́bù sì fún un ní ìṣun òkè àti ìṣun ìṣàlẹ̀.