Judges 1:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Juda bá àwọn ọmọ Simeoni, arakunrin wọn, lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí wọ́n ń gbé Sefati. Wọ́n gbógun tì wọ́n, wọ́n run wọ́n patapata, wọ́n sì sọ ìlú náà ní Horima.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Juda si bá Simeoni arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si pa awọn ara Kenaani ti ngbé Sefati, nwọn si pa a run patapata. A si pè orukọ ilu na ni Horma.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, àwọn ológun Júdà tẹ̀lé àwọn ológun Ṣíméónì arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé Ṣéfátì jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátapáta, ní báyìí à ò pe ìlú náà ní Hómà (Hómà èyí tí ń jẹ́ ìparun).