Judges 1:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn amí náà rí ọkunrin kan tí ń jáde bọ̀ láti inú ìlú náà, wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, fi ọ̀nà tí a óo gbà wọ ìlú yìí hàn wá, a óo sì ṣe ọ́ lóore.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn amí na si ri ọkunrin kan ti o ti inu ilu na jade wá, nwọn si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, fi ọ̀na atiwọ̀ ilu yi hàn wa, awa o si ṣãnu fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àti wọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mìí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.”