Judges 1:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Manase kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣeani ati àwọn ará Taanaki jáde, ati àwọn ará Dori, àwọn ará Ibileamu, àwọn ará Megido ati àwọn tí wọn ń gbé gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú náà; ṣugbọn àwọn ará Kenaani ṣì ń gbé ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Manasse kò si lé awọn ara Beti-seani ati ilu rẹ̀ wọnni jade, tabi awọn ara Taanaki ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Dori ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Ibleamu ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Megiddo ati ilu rẹ̀ wọnni: ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹ̀yà Mánásè sì kùnà láti lé àwọn tí ń gbé Bẹti-Sésínì àti àwọn ìlú agbègbè wọn jáde, tàbí àwọn ará Tánákì àti àwọn ìgbéríko rẹ̀, tàbí àwọn olùgbé Mégídò àti àwọn ìgbéríko tí ó yí i ká torí pé àwọn ará Kénánì ti pinnu láti máa gbé ìlú náà.