Judges 1:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Juda bá tọ ẹ̀yà Simeoni, arakunrin wọn lọ, wọ́n ní, “Ẹ bá wa lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wa, kí á lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani. Nígbà tí ó bá yá, àwa náà yóo ba yín lọ síbi ilẹ̀ tí wọ́n pín fun yín.” Àwọn ẹ̀yà Simeoni bá tẹ̀lé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Juda si wi fun Simeoni arakunrin rẹ̀ pe, Bá mi gòke lọ si ilẹ mi, ki awa ki o le bá awọn ara Kenaani jà; emi na pẹlu yio si bá ọ lọ si ilẹ rẹ. Simeoni si bá a lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Júdà béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ṣíméónì arákùrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kénánì jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ ogun Síméónì sì bá àwọn ọmọ ogun Júdà lọ.