Judges 1:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Nafutali kò lé àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati àwọn ará Betanati jáde, ṣugbọn wọ́n ń gbé ààrin àwọn tí wọ́n bá ni ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn wọ́n ń fi tipátipá kó àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ati ti Betanati ṣiṣẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Naftali kò lé awọn ara Beti-ṣemeṣi jade, tabi awọn ara Beti-anati; ṣugbọn on ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: ṣugbọn awọn ara Beti-ṣemeṣi ati Beti-anati di ẹniti nsìn wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹ̀yà Náfítalì pẹ̀lú kò lé àwọn ará Bétì-Ṣémésì àti Bẹti-Ánátì jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Náfítanì náà ń gbé àárin àwọn ará Kénánì tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Bẹti-Ṣéméṣì àti Bẹti-Ánátì ń sìn ìsìn tipátipá.