Judges 1:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Amori kọ̀, wọn kò jáde ní òkè Heresi, Aijaloni ati Ṣaalibimu, ṣugbọn àwọn ọmọ Josẹfu kò fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀ títí tí àwọn ọmọ Josẹfu fi bẹ̀rẹ̀ sí fi tipátipá kó wọn ṣiṣẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Amori si ngbé òke Heresi, ni Aijaloni, ati ni Ṣaalbimu: ọwọ́ awọn ara ile Josefu bori, nwọn si di ẹniti nsìn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Ámórì ti pinnu láti dúró lórí òkè Hérésì àti òkè Áíjálónì àti ti Ṣáíbímù, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Jósẹ́fù di alágbára wọ́n borí Ámórì wọ́n sì mú wọn sìn.