Judges 1:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Juda gbéra, wọ́n lọ gbógun ti àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. OLUWA fi wọ́n lé àwọn ọmọ Juda lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹgun ẹgbaarun (10,000) ninu wọn ní Beseki.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Juda si gòke lọ; OLUWA si fi awọn ara Kenaani ati awọn Perissi lé wọn lọwọ: nwọn si pa ẹgbarun ọkunrin ninu wọn ni Beseki.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Júdà sì kọ lu àwọn ọmọ Kénánì, OLÚWA ran àwọn Júdà lọ́wọ́, ó sì fi àwọn ará Kénánì àti àwọn ará Párísì lé wọn lọ́wọ́, àwọn Júdà sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Béṣékì nínú àwọn ọ̀ta wọn.