Judges 1:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Adonibeseki bá dáhùn pé, “Aadọrin ọba tí mo ti gé àtàǹpàkò ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ wọn, ni wọ́n máa ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tabili mi. Ẹ̀san ohun tí mo ṣe sí wọn ni Ọlọrun ń san fún mi yìí.” Wọ́n bá mú un wá sí Jerusalẹmu, ibẹ̀ ni ó sì kú sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Adoni-beseki si wipe, Adọrin ọba li emi ke li àtampako ọwọ́ wọn ati ti ẹsẹ̀ wọn, ti nwọn nṣà onjẹ wọn labẹ tabili mi: gẹgẹ bi emi ti ṣe, bẹ̃li Ọlọrun si san a fun mi. Nwọn si mú u wá si Jerusalemu, o si kú sibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ó wí pé, àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń sa ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí OLÚWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn, wọ́n sì mú un wá sí Jérúsálẹ́mù ó sì kú sí bẹ̀.