Judges 1:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, wọ́n gbógun ti àwọn ará ilẹ̀ Kenaani tí wọ́n ń gbé orí òkè, ati ìhà gúsù tí à ń pè ní Nẹgẹbu, ati àwọn tí wọn ń gbé ẹsẹ̀ òkè náà pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin na awọn ọmọ Juda si sọkalẹ lọ lati bá awọn ara Kenaani jà, ti ngbé ilẹ òke, ati ni Gusù, ati ni afonifoji nì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní Gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀ oòrùn Júdà jagun.