Judges 10:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà Gileadi sì bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Ta ni yóo kọ́kọ́ ko àwọn ọmọ ogun Amoni lójú?” Wọ́n ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kò wọ́n lójú ni yóo jẹ́ olórí fún gbogbo àwa ará Gileadi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia na, awọn olori Gileadi si wi fun ara wọn pe, ọkunrin wo ni yio bẹ̀rẹsi bá awọn ọmọ Ammoni jà? on na ni yio ṣe olori gbogbo awọn ara Gileadi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìjòyè: aṣíwájú àwọn ará Gílíádì wí fún ará wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí yóò kọ́ sígun si àwọn ará Ámónì ni yóò jẹ́ orí fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní Gílíádì.”