Judges 10:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, ati Aṣitarotu, oriṣa àwọn ará Siria ati àwọn ará Sidoni, ti àwọn ará Moabu ati àwọn ará Amoni, ati ti àwọn ará Filistia. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò sìn ín mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu, ati Aṣtarotu, ati awọn oriṣa Siria, ati awọn oriṣa Sidoni, ati awọn oriṣa Moabu, ati awọn oriṣa awọn ọmọ Ammoni, ati awọn oriṣa awọn Filistini; nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn kò si sìn i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLÚWA. Wọ́n sin Báálì àti Áṣítórétù àti àwọn òrìṣà Árámù, òrìṣà Ṣídónì, òrìṣà Móábù, òrìṣà àwọn ará Ámónì àti òrìṣà àwọn ará Fílístínì. Nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì kọ OLÚWA sílẹ̀ tí wọn kò sì sìn-ín mọ́,