Judges 11:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba Amoni bá rán àwọn oníṣẹ́ pada sí Jẹfuta pé, “Nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ gba ilẹ̀ mi, láti Anoni títí dé odò Jaboku, títí lọ kan odò Jọdani. Nítorí náà, ẹ yára dá ilẹ̀ náà pada ní alaafia.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba awọn ọmọ Ammoni si da awọn onṣẹ Jefta lohùn pe, Nitoriti Israeli ti gbà ilẹ mi, nigbati nwọn gòke ti Egipti wá, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati titi dé Jordani: njẹ́ nisisiyi fi ilẹ wọnni silẹ li alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba àwọn Ámónì dá àwọn oníṣẹ́ Jẹ́fità lóhùn pé, “Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ti Éjíbítì wá. Wọ́n gba ilẹ̀ mi láti Ánónì dé Jábókù, àní dé Jọ́dánì, nítorí náà dá wọn padà lọ ní àlàáfíà àti ní pẹ̀lẹ́ kùtù.”