Judges 11:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rán oníṣẹ́ sí ọba Edomu, wọ́n ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ yín kọjá.’ Ṣugbọn ọba Edomu kò gbà wọ́n láàyè rárá, bákan náà, wọ́n ranṣẹ sí ọba Moabu, òun náà kò fún wọn láàyè, àwọn ọmọ Israẹli bá jókòó sí Kadeṣi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Israeli rán onṣẹ si ọba Edomu, wipe, Mo bẹ̀ ọ, jẹ ki emi ki o kọja ni ilẹ rẹ: ṣugbọn ọba Edomu kò gbọ́. Bẹ̃ gẹgẹ o si ranṣẹ si ọba Moabu pẹlu: ṣugbọn kò fẹ́: Israeli si joko ni Kadeṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí ọba Édómù pé, ‘Gbà fún wa láti gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá,’ ṣùgbọ́n ọba Édómù kò fetí sí wọn. Wọ́n tún ránṣẹ́ sí ọba Móábù bákan náà òun náà kọ̀. Nítorí náà Ísírẹ́lì dúró sí Kádésì.