Judges 11:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni o rìn lãrin aginjù o si yi ilẹ Edomu, ati ilẹ Moabu ká, o si yọ ni ìha ìla-õrùn ilẹ Moabu, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ṣugbọn nwọn kò wá sinu àla Moabu, nitoripe Arnoni ni àla Moabu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wọ́n rin ihà kọjá, wọ́n pẹ́ àwọn ilẹ̀ Édómù àti ti Móábù sílẹ̀, nígbà tí wọ́n gba apá ìlà oòrùn Móábù, wọ́n sì tẹ̀dó sí apá kejì Ánónì. Wọn kò wọ ilẹ̀ Móábù, nítorí pé ààlà rẹ̀ ni Ánónì wà.