Judges 11:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Israẹli bá tún rán oníṣẹ́ sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ó wà ní ìlú Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí agbègbè ilẹ̀ tiwa.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn Amori, ọba Heṣboni; Israeli si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o kọja lãrin ilẹ rẹ si ipò mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà ni Ísírẹ́lì rán àwọn oníṣẹ́ sí Síhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ń ṣe àkóso ní Hésíbónì, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Jẹ́ kí a la ilẹ̀ rẹ kọja lọ sí ibùgbé wa.’