Judges 11:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn iyawo Gileadi gan-an bí àwọn ọmọkunrin mìíràn. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin wọnyi dàgbà, wọ́n lé Jẹfuta jáde, wọ́n sọ fún un pé, “O kò lè bá wa pín ninu ogún baba wa, nítorí ọmọ obinrin mìíràn ni ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aya Gileadi si bi awọn ọmọkunrin fun u; nigbati awọn ọmọ aya na si dàgba, nwọn si lé Jefta jade, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ki yio jogún ni ile baba wa; nitoripe ọmọ ajeji obinrin ni iwọ iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìyàwó Gílíádì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un, nígbà tí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí dàgbà, wọ́n rán Jẹ́fità jáde kúrò nílé, wọ́n wí pé, “Ìwọ kì yóò ní ogún kankan ní ìdílé wa, nítorí pé ìwọ jẹ́ (ọmọ aṣẹ́wó) ọmọ obìnrin mìíràn.”