Judges 11:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Sihoni kò ní igbẹkẹle ninu àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ̀. Ó bá kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jahasi, wọ́n sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Sihoni kò gbẹkẹle Israeli lati kọja li àgbegbe rẹ̀: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo enia rẹ̀ jọ, nwọn si dó ni Jahasi, nwọn si bá Israeli jagun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Síhónì kò gba Ísírẹ́lì gbọ́ (kò fọkàn tán an) láti jẹ́ kí ó kọjá. Ó kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, ó sì tẹ̀dó sí Jáhásì láti bá Ísírẹ́lì jagun.