Judges 11:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jẹfuta bá sá jáde kúrò lọ́dọ̀ àwọn arakunrin rẹ̀, ó ń gbé ilẹ̀ Tobu. Àwọn aláìníláárí ati àwọn oníjàgídíjàgan kan bá kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá ń bá a digun jalè káàkiri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jefta sá kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, on si joko ni ile Tobu: awọn enia lasan si kó ara wọn jọ sọdọ Jefta, nwọn si bá a jade lọ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́fità sì sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, ó sì pàgọ́ sí ilẹ̀ Tóbù, ó sì ń gbé níbẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn ènìyàn kan ti ń tẹ ofìn lójú para pọ̀ láti máa tẹ̀lé e kiri.