Judges 11:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nígbà tí mo bá ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣẹgun wọn tán, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ jáde láti wá pàdé mi láti inú ilé mi, yóo jẹ́ ti ìwọ OLUWA, n óo sì fi rú ẹbọ sísun sí ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, ohunkohun ti o ba ti oju-ilẹkun ile mi wá ipade mi, nigbati emi ba ti ọdọ awọn Ammoni pada bọ̀ li alafia, ti OLUWA ni yio jẹ́, emi o si fi i ru ẹbọ sisun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde láti ẹnu ọ̀nà mi láti wá pàdé mi, nígbà tí èmi bá ń padà bọ̀ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọmọ Ámónì yóò jẹ́ ti OLÚWA, èmi yóò sì fi rúbọ bí ọrẹ ẹbọ ṣíṣun.”