Judges 11:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jefta si bọ̀ si ile rẹ̀ ni Mispa, si kiyesi i, ọmọbinrin rẹ̀ si jade wá ipade rẹ̀ ti on ti timbrili ati ijó: on nikan si li ọmọ rẹ̀; lẹhin rẹ̀ kò ní ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jẹ́fítà padà sí ilé rẹ̀ ní Mísípà, wò ó, ọmọ rẹ̀ obìnrin ń jáde bọ̀ wá pàdé rẹ̀ pẹ̀lú taboríìnì àti ijó. Òun ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó ní: kò ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn yàtọ̀ sí òun nìkan.