Judges 11:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe nigbati o ri i, o fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Yẽ, ọmọ mi! iwọ rẹ̀ mi silẹ gidigidi, iwọ si li ọkan ninu awọn ti nyọ mi lẹnu: nitori emi ti yà ẹnu mi si OLUWA, emi kò si le pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà tí ó rí i ó fa aṣọ rẹ̀ ya ní ìbànújẹ́, ó sì ké wí pé, “Háà! Ọ̀dọ́mọbìnrin mi, ìwọ fún mi ní ìbànújẹ́ ọkàn ìwọ sì rẹ̀ mí sílẹ̀ gidigidi, nítorí pé èmi ti ya ẹnu mi sí OLÚWA ní ẹ̀jẹ́, èmi kò sì le ṣẹ́ ẹ̀jẹ́ mi.”