Judges 11:37 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun baba rẹ̀ pe, Jẹ ki a ṣe nkan yi fun mi: jọwọ mi jẹ li oṣù meji, ki emi ki o lọ ki emi si sọkalẹ sori òke, ki emi ki o le sọkun nitori ìwa-wundia mi, emi ati awọn ẹgbẹ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n yọ̀ǹda ìbéèrè kan yìí fún mi, gbà mí láàyè oṣù méjì láti rìn ká orí àwọn òkè, kí n ṣunkún pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ mi torí mo jẹ́ wúndíá tí n kò sì ní lè ṣe ìgbéyàwó.”