Judges 11:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Lọ. O si rán a lọ niwọn oṣù meji: o si lọ, ati on ati awọn ẹgbẹ rẹ̀, o si sọkun nitori ìwa-wundia rẹ̀ lori òke wọnni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́fítà dá lóhùn pé, “Ìwọ lè lọ.” Ó sì gbà á láàyè láti lọ fún oṣù méjì. Òun àti àwọn ọmọbìnrin yóòkù lọ sí orí àwọn òkè, wọ́n ṣunkún nítorí pé kì yóò lè ṣe ìgbéyàwó.