Judges 11:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn àgbààgbà Gileadi dá a lóhùn pé, “Ìyọnu tí ó dé bá wa náà ni ó mú kí á wá sọ́dọ̀ rẹ; kí o lè bá wa lọ, láti lọ gbógun ti àwọn ará Amoni. Ìwọ ni a fẹ́ kí o jẹ balogun gbogbo àwa ará Gileadi patapata.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn àgba Gileadi si wi fun Jefta pe, Nitorina li awa ṣe pada tọ̀ ọ nisisiyi, ki iwọ ki o le bá wa lọ, ki o si bá awọn ọmọ Ammoni jà, ki o si jẹ́ olori wa ati ti gbogbo awọn ara Gileadi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìjòyè: àgbà Gílíádì dáhùn pé, “Nítorí rẹ̀ ni àwa fi yípadà sí ọ báyìí: tẹ̀lé wa, kí a lè dojú ìjà kọ àwọn ará Ámónì, ìwọ yóò sì jẹ olórí wa àti gbogbo àwa tí ń gbé ní Gílíádì.”