Judges 11:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí ẹ bá mú mi pada wálé, láti bá àwọn ará Amoni jagun, bí OLUWA bá sì fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ tí mo ṣẹgun wọn, ṣé ẹ gbà pé kí n máa ṣe olórí yín?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jefta si wi fun awọn àgba Gileadi pe, Bi ẹnyin ba mú mi pada lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti OLUWA ba si fi wọn fun mi, emi o ha jẹ́ olori nyin bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́fità dáhùn pé, “Bí ẹ̀yin bá mú mi padà láti bá àwọn ará Ámónì jà àti tí OLÚWA bá fi wọ́n lé mi lọ́wọ́: ṣe èmi yóò jẹ́ olórí yín nítòótọ́.”