Judges 12:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Efuraimu múra ogun, wọ́n ré odò Jọdani kọjá lọ sí Safoni. Wọ́n bi Jẹfuta léèrè pé, “Kí ló dé tí o fi rékọjá lọ sí òdìkejì láti bá àwọn ará Amoni jagun tí o kò sì pè wá pé kí á bá ọ lọ? Jíjó ni a óo jó ilé mọ́ ọ lórí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN ọkunrin Efraimu si kó ara wọn jọ, nwọn si kọja si ìha ariwa; nwọn si wi fun Jefta pe, Ẽṣe ti iwọ fi rekọja lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti iwọ kò si pè wa ki awa ki o le bá ọ lọ? awa o fi iná kun ile rẹ mọ́ ọ lori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin Éfúráímù pe àwọn ológun wọn jáde, wọ́n sì rékọjá sí Sáfónì, wọ́n sì bi Jẹ́fítà pé, “Èéṣe tí o fi lọ bá àwọn ará Ámónì jagun láì ké sí wa láti bá ọ lọ? Àwa yóò ṣun ilé rẹ mọ́ ọ lórí.”