Judges 12:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo sì ti mọ̀ pé ẹ kò tún ní gbà wá sílẹ̀, ni mo ṣe fi ẹ̀mí mi wéwu, tí mo sì kọjá sí òdìkejì lọ́dọ̀ àwọn ará Amoni; OLUWA sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Kí ló wá dé tí ẹ fi dìde sí mi lónìí láti bá mi jà?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati emi si ri pe ẹnyin kò gbà mi, mo fi ẹmi mi wewu, emi si rekọja sọdọ awọn ọmọ Ammoni, OLUWA si fi nwọn lé mi li ọwọ́: nitori kini ẹnyin ha ṣe gòke tọ̀ mi wá li oni, lati bá mi jà?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo ríi pé ẹ̀yin kò ṣetán láti ṣe ìrànlọ́wọ́, mo fi ẹ̀mi mi wéwu. Mó sì gòkè lọ láti bá àwọn ará Ámónì jà, OLÚWA sì fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn, Èéṣe báyìí tí ẹ fi dìde wá lónìí láti bá mi jà?”