Judges 12:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jẹfuta bá kó gbogbo àwọn ọkunrin Gileadi jọ, wọ́n gbógun ti àwọn ará Efuraimu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, nítorí pé àwọn ará Efuraimu pe àwọn ará Gileadi ní ìsáǹsá Efuraimu, tí ó wà láàrin ẹ̀yà Efuraimu ati ẹ̀yà Manase.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jefta kó gbogbo awọn ọkunrin Gileadi jọ, o si bá Efraimu jà: awọn ọkunrin Gileadi si kọlù Efraimu, nitoriti nwọn wipe, Isansa Efraimu li ẹnyin ara Gileadi iṣe, lãrin Efraimu, ati lãrin Manasse,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́fítà sì pe àwọn ọkùnrin Gílíádì, wọ́n sì bá àwọn ará Éfúráímù jà. Àwọn ará Gílíádì run wọ́n nítorí pé àwọn ará Éfúráímù ti ṣọ tẹ́lẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ará Gílíádì jẹ́ àṣáwọ̀ (ìṣáǹṣá) àwọn ará Éfúráímù àti ti Mànásè.”