Judges 12:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Gileadi gba àwọn ipadò odò Jọdani lọ́wọ́ àwọn ará Efuraimu. Nígbà tí ìsáǹsá ará Efuraimu kan bá ń sá bọ̀, tí ó bá sọ fún àwọn ará Gileadi pé, “Ẹ jẹ́ kí n rékọjá.” Àwọn ará Gileadi á bi í pé, “Ǹjẹ́ ará Efuraimu ni ọ́?” Bí ó bá sọ pé, “Rárá,”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Gileadi si gbà iwọdo Jordani ṣiwaju Efraimu: o si ṣe, nigbati awọn isansa Efraimu ba wipe, Jẹ ki emi ki o rekọja, awọn ọkunrin Gileadi a si wi fun u pe, Efraimu ki iwọ iṣe? Bi on ba si wipe, Rárá o!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Gílíádì gba àbáwọdò Jọ́dánì tí wọ́n máa gbà lọ sí Éfúráímù, nígbàkígbà tí àwọn ará Éfúráímù bá wí pé, “Jẹ́ kí ń sá lọ sí òkè,” lọ́hùn ún àwọn ará Gílíádì yóò bi í pé, “Ṣé ará Éfúráímù ni ìwọ ń ṣe?” Tí ó bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,”