Judges 12:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọn á ní kí ó pe, “Ṣiboleti.” Tí kò bá le pè é dáradára, tí ó bá wí pé, “Siboleti,” wọn á kì í mọ́lẹ̀, wọn á sì pa á létí odò Jọdani náà. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe pa ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa (42,000) eniyan, ninu àwọn ará Efuraimu ní ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn a si wi fun u pe, Njẹ wi pe Ṣibboleti; on si wi pe Sibboleti, nitoripe on kò le pè e rere; nwọn a si mú u, nwọn a si pa a si iwọdo Jordani: awọn ti o si ṣubu li akokò na ninu awọn Efraimu jẹ́ ẹgbã mọkanlelogun enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣhíbólétì.’ ” Tí ó bá ní, “Síbólé,” tì torí pé kò ní mọ̀ọ́ pé dáadáa, wọ́n á mú-un wọn, a sì pa á ni àbáwọdò Jọ́dánì. Àwọn ará Éfúráímù tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléní-ogójì ọkùnrin.