Judges 12:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bí ọmọkunrin mejilelọgbọn, ó sì ní ọgbọ̀n ọmọbinrin. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ obinrin fọ́kọ láàrin àwọn tí wọn kì í ṣe ìbátan rẹ̀, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin láti inú ẹ̀yà mìíràn wá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin. Ó jẹ́ aṣiwaju ní Israẹli fún ọdún meje.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si lí ọgbọ̀n ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọbinrin ti on rán lọ si ode, o si fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin lati ode wá fi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀. On si ṣe idajọ Israeli li ọdún meje.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó ní ọgbọ̀n (30) ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ó ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún méje.