Judges 13:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Wọ́n sin àwọn ará Filistia fún ogoji ọdún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA; OLUWA si fi wọn lé awọn Filistini li ọwọ́ li ogoji ọdún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún ṣe ohun tí ó burú ní ojú OLÚWA, OLÚWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Fílístínì lọ́wọ́ fún ogójì (40) ọdún.