Judges 13:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Manoa bá gbéra, ó bá tẹ̀lé iyawo rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó bi í pé, “Ṣé ìwọ ni o bá obinrin yìí sọ̀rọ̀?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Manoa si dide, o si tẹle aya rẹ̀, o si wá sọdọ ọkunrin na, o si bi i pe, Iwọ li ọkunrin na ti o bá obinrin na sọ̀rọ? On si wipe, Emi ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mánóà yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, “Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀?” Ọkùnrin náà dáhùn pé “Èmi ni.”